Quantcast
Channel: Àṣà Oòduà Archives - Ọmọ Oòduà
Viewing all 1429 articles
Browse latest View live

Idile Alayo Toni 09.06.2016

$
0
0

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Idile Alayo wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Idile Alayo ti ose yi. Beeni mo ki gbogbo awa musulumi ododo wipe a ku ongbe o, emi wa ti o bere re ni yoo pari re lase Edumare.

E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.

Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-

“Olootu mo ki yin pupo fun ise takuntakun ti e n se lori eto yi, Eledua yoo tun ile ati ona tiyin na se o, mo si ki gbogbo awa ololufe eto Idile Alayo wipe ile alayo gbogbo wa ko ni di ibanuje lase Edumare. Ase

Olootu oro kan ni o n dun mi lokan ti mo nilo amoran awon ojogbon, odun iketa ree ti mo ti wa nile oko, ti Eledua si ti fi omo kan da mi lola, ise awon ti nko ile ni oko mi nse ti Eledua si gba fun un lenu ise owun. Ko si ipinle na ni orile ede wa nibi ti oko mi kii tii lo se ise, nse ni won ma n pee lotun losi tofi je wipe oko mi le lo ni osu kan si meji nigba miran laiwa si ile.

Looto kii se wipe bi ise se maa n gbe arakunrin yi kiri yi ko dun mo mi ninu nitori mo mo wipe atije atimu ni o nba ka beeni mo si ti mo arakunrin yi pelu ise re ki n to fe e, sugbon ohun kan ti o n sele ti o si n kan mi lominu ni wipe o fere je akoko ti oko mi ko ba si nile pelu mi ni inu mi ma n dun wipe mo ni oko, o fere je akoko yi nikan ni mo ma n ri ayo ile oko, o fere je akoko yi nikan ni mo le fi oko mi yanga sugbon ni kete ti oko mi ba pada de nse ni ebi wa ma n di ebi alariwo.

Oro yi si wa n je edun okan fun mi, tori ti oko mi ba wa ni irin ajo nse ni yoo maa ba mi soro lori ero ibanisoro bi eni wipe laisi emi ko si oun pelu, nse ni awa mejeeji yoo ma da oweke lori ago, opolopo oro apani lerin, opolopo amoran, ati oro tutu lolokan ojokan ni oko mi yoo maa so simi toje ti mo ba soro pelu oko mi tan inu mi a si maa dun, maa si ma dupe lowo ori mi ti o gbe mi pade arakunrin yi sugbon ni kete ti oko mi ba pada sile ni oro yoo wa yi pada. Emi ati oko mi yoo wa maa sebi ologbo ati ekute ninu ile.

Oro yi a si maa gba omije loju mi lopo igba tori nse ni mo n ro wipe se nkan miran wa nidi oro yi ni? Koda mo ti gbawe gbadura lori oro yi sugbon ko si ayipada, opolopo igba ni mo ti ji oko mi ni oganjo oru ti mo si bii leere wipe ki ni ma nfa sababi ede aiyede wa gan ti yoo si daun wipe emi ni mo ma n faa, nje ona wo ni mo fi ma nfa gan? Ni yoo ba wipe ki n lo ye ara mi wo.

Oro yi le ma ni itunmo si elomiran sugbon ohun ti n gba omije loju mi gan ni, abi ewo ni ki eniyan ri oko re ti o ye ki o je idunnu re ti yoo si wa je ibanuje fun oluware, ti a ba si n soro lori ago nse ni yoo dabi eni wipe awa ni loko laya ti o dara Julo ni agbaye. Beeni awon oro ti ko to nkan ni o si ma n saba da gbonmi si omi o to yi si. Oro yi ti wa toju sumi pata pata bayi, iyen ni mo se ni ki n fi lo eyin iya ati baba mi ti e mo nipa oro loko laya tori won ni iriri sagba ogbon.

E jowo ki ni ma n se okunfa iru isele yi gan ati pelu ki ni ona abayo, e dakun eyin oloye eniyan, e la mi loye o”

Hmmm oro ree o eyin ojogbon ati oloye eto idile alayo, aja ti o ri olowo re lokere, ti o si kun fayo, ti o nfo soke sile ti olowo re wa sun moo tan ti ngbo fita fita, se aja ni ki a da lebi ni abi olowo re ni ki o ye ara re wo? Eyin ojogbon o dowo yin o

`Abel Simeon Oluwafemi


Ire otun, ire osi, ire niwa..Iree o

$
0
0

Iree! Apa mejeeji l’eyele fi n ko’ree wo’le. Ire otun, ire osi, ire niwa, ire l’eyin, ire Olokun, ire Olosa, ko mi a da giriri wole to wa wa!
Aase!

Iwure Owuro 12.06.2016

$
0
0

E MAA WI TELE MI :

*Ori mi wa gbe mi leke abinu eni.
*Ori mi ko ni gbabode ibi.
*Oloore mi ko ni ri mi sa
*Oluwa so egan mi dogo.

*Edumare wa fi ibukun sinu ise mi

*Lojo tebi n pa ile, emi ko ni si nile

*Lojo tebi n pa ona, emi ko ni rin lona(ASE)

 

Arewa Asa Toni

$
0
0

Ayeye Ojo Ibi Iyawa Toyin Adewale

Ojo ibi se koko Ojo ibi se pataki eo ni mo Ojo ibi yin
saburu,Ododun ni sapo nruwe Ododun ni mariwo yo
Ododun la nri omo obi lori ate, emi yin o se opo
odun laiye ooo…. Igba Odun Odun kan nio…. Ire
oooo

toyin

Akara Imora’n toni – 09.07.2016

$
0
0

*Emi ko ni ku saaju ojo ayo mi.*Emi ko ni fi ewon logba.*Iji aye ko ni gbe mi lo(Ase Edumare).
………….
‪#‎AKARA_IMORAN‬ : Gbiyanju lati ni iwe iranti fun awon olooore re; ki o si gbiyanju lati fa iwe asise awon to se o ya. Ranti pe awon kan ni iwo naa se, ti won darijin iwo naa. Ayo ni ooo.

lati owo Aare Olasunkanmi Alani Agbasaga

Ogulutu Oro Toni – 09.07.2016

$
0
0

Hummmmmmmm igbiyanju lagbe ngba Olohun lomu
isu ta
‪#‎woo_orewa‬
Nje o mo pe eni tio sun(sleep) lo nsun(move)?????
???
Gbiyanju lati tesiwaju loni majeki ijakule re fao seyin
nigbesi aiye re
‪#‎gbomi_dada‬
Koseni tio ni ‪#‎sugbon‬ tie gboju re kuro nibi oro
awon elegan loni kio si tesiwaju yio dara fun oooo
,……ire ooo

 

King Ogulutu Oro

Awo Ori – Odu Odi Meji

$
0
0

Odidi kirimu kirimu, Awo Ori
A difa fun Ori
Ori n be logbere oun nikan
Ebo won ni kowa se
O gbebo nibe O rubo
Kerekere Oju wa, Eti wa, Imu wa, Enu wa
Gbogbo won wa ba Ori duro
Ori wa asa lai di eleni
Odidi Kirimu kirimu, Awo Of Ori

Cast For Ori

When Ori was Living In Isolation
He Was Asked To Offer Sacrifice
And He Complied
Bit By Bit Eyes, Ear, Nose, Mouth Came To Stay With Ori
Our Ori(Spiritual/Inner Head) Will No Longer Live in Isolation…. ASE IRE O!
Holy Odu Odi Meji!!!!!!!

Iyalorisa Omitonade Ifawemimo

Gbogbo wa ni o bo ikin la! Aase!

$
0
0

IFA NI Asese roko agbe adabi akiti ohun obo Adifafun Ajala yobo Ikin la lese oke ebo won ni kose ogbebo ni be osebo bi kasai bokinla olowo Ajala bi kasai bo Ikinla emin ateyin ololufemi gbogbo wa labo ikin la Aku ose ifa toni Obi wa yoyan Amari Ikin wa bo Aribe Asebe.

 

 

`IyaOgbe OmoEdu Yeyelufe Oyewole


Ejowo eni to ba mo olorin yi ko ko oruko re

Foto ode’oni – 13.07.2016

$
0
0

Saheed osupa akorede ati baba wande.

saheed

Oniwowo ado! Baba dakun ma na mi o! Aase!

$
0
0

OBALUAYE!!!!!! OOOOOOO

cc- Babalawo Ifakayode Oyedele Osaifa

Elesin Oyan

$
0
0

Iba Orunmila Bara Agbonniregun;
Elesin Oyan;
Adagbaa Ojomu;
Gbolajoko Omo Ere l’apa;
Baba Okinkin ti n m’eyin erin fo;
Odudu tii du ori emere ti o je ko fo;
Atori eni ti ko sunwon se!
Iba Baba o!

Ojumo Ire

$
0
0

B’ojumo ba mo ..
Ooye a la ‪#‎peregede‬..
A D’ifa fun Peregede tii se yeye ‪#‎Ojumo‬ .
A KU OJUMO
#Ojumo to mowa Lonii.
‪#‎Ojumo_Ire‬ gbogbo ni yoo je funwa lase Oba mi
Oke .

Olojo Ibi Toni

$
0
0

Mo layo lati so fun yin wipe oni ni ojo ibi Alfa Ola Akeem Totofun’un ti won je okan pataki ninu ebi Ooduarere.
Olojo ibi oni a ki yin e ku ayo oni, e o se pupo re laye ninu alafia ara ati ibale okan. Ni oruko Eledumare e o ni ba won na oja warawara nile aye beeni e o si ni dagba yeye, gbogbo ohun rere ti n mu’le aye rorun fun eda ni Eledua yoo fi jinki yin. E o gbo, e o to, e o fewu pari, e o ferigi jobi, e o gbele aye sohun rere bi o ti wa wu ki e pe to laye e o ni f’oju mo saare omo lase Edumare.

Kabiyesi ati awon Oloye ati gbogbo ebi Omo Oodua rere pata nileloko nki yin wipe IGBA ODUN, ODUN KAN NI O…

Ewesooo Dede Ewen Goons Mi


Iyawo: mi o le gba ki iya oko mi gbe pelu mi lailai.

$
0
0

Olotu:kini ikan tori tofi ni o le gba ki iya gbe pelu re,gbogbo awon eyan loti ba e so,o ko,o loni gbo,won tun gbe e wa sori afefe,agidi yi nan lotun lo.Kini ikan to sele gan.
Iyawo:seri olotu,mole gba ki gbogbo eyan wasi ile wa o,amon iya oko mi,mi o le gba o.Ti oko mi bafe ri iya re,ko losi ile re,ti iya oko mi nan bade feri wa ki won pe wa,awa bawon,amonpe won o wa sile wa mi o ni gba o.
Olotu:dakun arabinrin kini ikan ti iya oko re se fun o,tofi ni o feri won,sebi obinrin ni iwo nan ranti pe iwo nan a dagba.Mofi eledumare be o,salaye fun wa.
Iyawo:hun o ma ga o,tiko baki se olorun tefi be mi,mi o bama ti gbo,tori iya oko mi kose mi,amon ti moba dake tara mi nan a bami dake ni.Olotu kin tole so ikankan,mofe ki gbogbo ebi oko mi peju ati iya oko mi,igba nan ni mato soro.
Olotu:oda koburu,a fun o laye,amon eyin ara ile kini eyin rope o be ninu arabinrin yi,tori won royin gbogbo ikan ti iya oko re sefun.Humm ile aye gbege oo.O dabo.
Eku ojo meta gbogbo o

Ounje emi fun t’ooro yii ( 20 – 07 – 2016 )

$
0
0


HUN !!!
# Odo to gbagbe # Orisun …
Gbigbe nii gbe …

WOO ORE WA !!!
Ibi  Ipile eda L’orisun won..
Ibi  Eniyan ti lalehu ni Ipile re…
Eni to bini Orisun‬ eni nii se…
Eniyan‬ to wo’ni dagba Ipile eni nii …
Eni a dijo Sewe di Agba orisun eni niwon..

GBOMI DAADAA ORE WA !!!
Ise , Eniyan tabi ohun kan to se Sababi  Ola
(re-mi), Ola (re-do) pelu ‪‎Ola‬ (do-re) Orisun
eni ni…
BEE,
Ilu ,  Agbegb ,  Ileto ati # Awujo ti a bini si
Orisun eni ni…

DAKUN ORE WA !!!
Maa se Iranti ibi ‪‎ipile‬ re…
Loo se Atunse si Orisun re..
A maa mu’ni tesiwaju …
…..
……
A KU OJUMO
Oni‬ a sanwa L’ase ‪‎EDUMARE‬ ..

 

Mc-Wayio Idunnuomo Presenter

Abi e roju aye bi?

$
0
0

Orewa nso fun ara ile wipe ki won
Ba oun gbe orin, sugbon won o da loun, lo ba binu lo
Si oko o da orin sugbon won o fun lounje, o tun lo si
Odo o da orin won o je ko we(bath) beni won o fun ni
Omi mu, o wa pada sinu ile o n sofun ara ile wipe se
Eo gbe orin a bi eo gbe orin? Orewa bi orin o ba fie
Si le boya kofi orin sile koye tan arare je. Toripe
Yoruba bo won ni, bi eniyan ba ‘ko orin ti
Orin nan ko dun sebi oun nan f’eti arare
Gbo. Orewa itumo asamo mi nipe iwa wo lon wu tofi
Je pe aye o gba tie nibi gbogbo? O ya fura ko ronu
Pi’wada ki ojo to lo, toripe aye yi o lo bi opa-
Ibon. Ibi araye ko oju si awa o ni ko eyin si.
Oju-itere ojulowo omo ooduarere

Odu ifa IROSUN ATAPO – Faniyi David Osagbami

$
0
0

 |    |
 |    |
| |  |
| | | |

 

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, bi a se njade lo laaro yi pelu ayo ati alaafia a koni pada sile pelu ibanuje o ase.
Odu ifa IROSUN ATAPO lo gate laaro yi, ifa yi fore fun akapo ti odu ifa yi ba jade si, ifa ni inu ise ati iya ni akapo yi wa sugbon ifa ni oun yio mu kuro nibe oun yio si mulo sinu oro, sugbon ifa yi kilo gidigidi fun akapo yi ki o mase silekun aseju leyin ti aye re bati wa dara tan ti o ti ni laari ki o ma baa pada sinu osi ati iya to wa tele.

 
Ifa naa ki bayi wipe: Orunmila ni gbongbo ta gongo dina a difa fun olobahun lojo ti o nbe ninu ise oun iya ijahanjahan igi oko ti won ni ki o karale ebo ni ki o wa se ki o baa le kuro ninu Iya to ngbe ki o ba le di olowo oloro sugbon won kin nilo wipe ti o bati di olowo oloro tan ki o mase silekun aseju o olobahun loun ti gbo , obi meji, eyele funfun, ekuru funfun, adiye funfun, otin olobahun rubo won si se sise ifa fun ko pe ko jina seni olobahun ba ara re ninu ile nla tokun fun gbogbo nkan meremere inu olobahun dun olobahun dolowo o doloro, selo di bi ojo melo kan sii seni olobahun ri lekun kan ninu ile to wa yen olobahun wa ndaro wipe ti oun ba silekun yi bayi boya oun a tie tun di oloro ju bayi lo seni olobahun lo silekun nigbati o maa wonu yara naa selo ba opolopo nkan meremere ile aye nibe to tun poju ti ibiti o wa tele lo o wa nwo OLOKUN to joko soju Omi, OLOKUN wa sope olobahun! Sebi won kilo fun e wipe ki o mase silekun aseju, olobahun wa bere sini be OLOKUN wipe ki o ma binu soun OLOKUN ba gba ipe olobahun o si lo olobahun wa bere aye iwo re jije o ni gbogbo oro ile aye patapata, ko tun pe ti olobahun tun ri lekun miran ninu yara to wa yen, bo se tun da ngbimoran niyen wipe ah! Oun tun maa silekun yi o oni inu Ibe gan ni oro ile aye maa pin si, bi olobahun se silekun niyen o to maa wole sinu yara bayi se lo ba ara re ninu apalapolo igi oko ti ibe se kiki idoti ati egbin pelu ijahanjanhan isepe igi olobahun bere sini da ara re lebi bi olobahun se pada sinu osi ayeraye niyen o, o wa bere sini nyin babalawo re layin sodi nje ko pe ko jina eyin ko wa rifa ojohun bo ti nse ifa de alase ebora abise ope abise wara.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe eledumare yio muwa kuro ninu ise ayeraye yio muwa wonu oro, ori wa yio gbewa dele olokun seni ade, ako ni siwawu ojukokoro ati aigbonran koni muwa pada sinu osi ayeraye o, eti wa koni di si ibawi o aaaseee.

 

 

English Version:

Good morning my people, how was your night? Hope it was fantastic, I pray as we are going out this morning with peace and joy, we shall not return back home with sadness ase.
It is IROSUN ATAPO corpus that revealed this morning, ifa foresee goodness for whoever this corpus revealed out for, ifa said this person will be take out of suffering life and put him/her in a good and treasury abode, ifa also warn this person not to misbehave whenever he/she is living fine so that he/she won’t go back into his/her wretch life.
Hear what the corpus said: Orunmila said the root spread buckled on the road it cast divined for tortoise when he was advised not to open a misbehaving door, this tortoise was living in poverty then and he was asked to offer sacrifice so that he could excel and became rich but he was warned not to misbehave when he become rich, two kola nuts, White hen, white pigeon, ekuru funfun, gin and he complied, suddenly tortoise just saw himself in a beautiful place that full up of treasure and he was so happy and started enjoying, when it was some days he found out there is another door inside the beautiful place that he was living and he was meditating that if he could open the door maybe he would be more wealthy than this, so he opened the door and he entered there and he found plenty things that is more than where he was living and he saw “OLOKUN” sitting on the top of ocean saying tortoise! And you have been warned not to open a misbehaving door, tortoise begged her not to be angry with him and OLOKUN accepted and she went away tortoise became rich plentifully he started enjoying a great life, in a few days he found another door in the treasury room and he also meditating as before that this place would be a very great place than where he has been living so far, tortoise had forgotten the warnings he opened the door again when he will entered the room he found himself in a corner of tree that full of dirty and dried stems of tree than where he was living when he was still wretched, tortoise was started blaming himself, this is how covetousness and misbehaving led tortoise back to wretched life.
My people, I pray this morning that God will take us from wretch home to treasury home, our head will lead us to house of OLOKUN and we shall never misbehave to return back to wretched life, our ears will never block to warnings ase.
ABORU ABOYE OOO.

 

Faniyi David Osagbami

Alaso funfun

Viewing all 1429 articles
Browse latest View live


Latest Images